Saamu 114:1-8
Biblica Open Yoruba Contemporary Bible (OYCB)
Israẹli jáde ní Ejibiti, àwọn orísun ìwà í rí i
Copyright (c) 2009, 2017 Biblica, Inc. CC BY-SA 4.0.
1Nígbà tí Israẹli jáde ní Ejibiti, ilé Jakọbu láti inú ènìyàn àjèjì èdè
2Juda wà ní ibi mímọ́, Israẹli wà ní ìjọba.
3Òkun sì rí i, ó sì wárìrì: Jordani sì padà sẹ́yìn.
4Àwọn òkè ńlá ń fò bí àgbò àti òkè kéékèèké bí ọ̀dọ́-àgùntàn.
5Kí ni ó ṣe ọ́, ìwọ Òkun, tí ìwọ fi wárìrì? Ìwọ Jordani, tí ìwọ fi padà sẹ́yìn?
6Ẹ̀yin òkè ńlá kí ló dé ti ẹ fi ń fò bí àgbò, àti ẹ̀yin òkè kéékèèké bí ọ̀dọ́-àgùntàn?
7Wárìrì, ìwọ ilẹ̀, níwájú Olúwa; ní iwájú Ọlọ́run Jakọbu
8tí ó sọ àpáta di adágún omi, àti òkúta-ìbọn di orísun omi.