Saamu 123:1-4
Biblica Open Yoruba Contemporary Bible (OYCB)
Àwọn ọmọ Olúwa ń wo ọwọ́ Rẹ̀
Copyright (c) 2009, 2017 Biblica, Inc. CC BY-SA 4.0.
1Ìwọ ní mo gbé ojú mí sókè sí, ìwọ tí ń gbé inú ọ̀run.
2Kíyèsi, bí ojú àwọn ìránṣẹ́kùnrin ti máa ń wo ọwọ́ àwọn baba wọn, àti bí ojú ìránṣẹ́bìnrin ti máa ń wo ọwọ́ ìyá rẹ̀ bẹ́ẹ̀ ni ojú wa ń wo Olúwa Ọlọ́run wa, títí yóò fi ṣàánú fún wa.
3Olúwa, ṣàánú fún wa, ṣàánú fún wa; nítorí tí a kún fún ẹ̀gàn púpọ̀púpọ̀.
4Ọkàn wa kún púpọ̀ fún ẹ̀gàn àwọn onírera, àti fún ẹ̀gàn àwọn agbéraga.