Saamu 131:1-3

Biblica Open Yoruba Contemporary Bible (OYCB)

Olúwa dá àyà mi, èmi sì sinmi ọkàn mi. Ìwọ Israẹli, ìrètí ni ti Olúwa.

Copyright (c) 2009, 2017 Biblica, Inc. CC BY-SA 4.0.

1Olúwa àyà mi kò gbéga, bẹ́ẹ̀ ni ojú mi kò gbé sókè: bẹ́ẹ̀ ni èmi kò fi ọwọ́ mi lé ọ̀ràn ńlá, tàbí lé ohun tí ó ga jù mí lọ.

2Nítòótọ́ èmi mú ọkàn mi sinmi, mo sì mú un dákẹ́ jẹ́ẹ́, bí ọmọ tí a ti ọwọ́ ìyá rẹ̀ gbà ní ẹnu ọmú: ọkàn mi rí gẹ́gẹ́ bí ọmọ tí a já ní ẹnu ọmú.

3Israẹli, ìwọ ní ìrètí ní ti Olúwa láti ìsinsin yìí lọ àti láéláé.