Heberu 3:1-19
Biblica Open Yoruba Contemporary Bible (OYCB)
1Nítorí náà ẹ̀yin ará mímọ́, alábápín ìpè ọ̀run, ẹ gba ti aposteli àti olórí àlùfáà ìjẹ́wọ́ wa rò, àní Jesu;
2ẹni tí o ṣe olóòtítọ́ si ẹni tí ó yàn án, bí Mose pẹ̀lú tí ṣe olóòtítọ́ nínú iṣẹ́ rẹ̀ gbogbo nínú ilé Ọlọ́run.
3Nítorí a ka ọkùnrin yìí ni yíyẹ sí ògo ju Mose lọ níwọ̀n bí ẹni tí ó kọ́ ilé ti lọ́lá ju ilé lọ.
4Láti ọwọ́ ènìyàn kan ni a sá à ti kọ́ olúkúlùkù ilé; ṣùgbọ́n ẹni tí ó kọ́ ohun gbogbo ni Ọlọ́run.
5Mose nítòótọ́ sì ṣe olóòtítọ́ nínú gbogbo iṣẹ́ rẹ̀ nínú ilé Ọlọ́run, bí ìránṣẹ́, fún ẹ̀rí ohun tí a ó sọ̀rọ̀ wọ́n ní ìgbà ìkẹyìn.
6Ṣùgbọ́n Kristi jẹ́ olóòtítọ́ gẹ́gẹ́ bí ọmọ lórí ilé Ọlọ́run; ilé ẹni tí àwa jẹ́, bí àwa bá gbẹ́kẹ̀lé e, tí a sì di ìṣògo ìrètí wa mu ṣinṣin títí dé òpin.
7Nítorí náà gẹ́gẹ́ bi Ẹ̀mí Mímọ́ tí wí: “Lónìí bí ẹ̀yin bá gbọ́ ohùn rẹ̀,
8ẹ má ṣe sé ọkàn yín le, bí ìgbà ìṣọ̀tẹ̀, bí i ní ọjọ́ ìdánwò ní aginjù,
9níbi tí àwọn baba yín ti dán mi wò, tí wọ́n sì rí iṣẹ́ mi ní ogójì ọdún.
10Nítorí náà a mú inú bí mi si ìran náà, mo sì wí pé, ‘Nígbà gbogbo ni wọn ṣìnà ní ọkàn wọn; wọn kò sì mọ ọ̀nà mi.’
11Bí mo tí búra nínú ìbínú mi, ‘Wọn kí yóò wọ inú ìsinmi mi.’ ”
12Ẹ kíyèsára, ará, kí ọkàn búburú ti àìgbàgbọ́ má ṣe wà nínú ẹnikẹ́ni yín, ní lílọ kúrò lọ́dọ̀ Ọlọ́run alààyè.
13Ṣùgbọ́n ẹ máa gba ara yín ní ìyànjú ní ojoojúmọ́, níwọ̀n ìgbà tí a bá ń pè ní “Òní,” kí a má ba à sé ọkàn ẹnikẹ́ni nínú yín le nípa ẹ̀tàn ẹ̀ṣẹ̀.
14Nítorí àwa di alábápín pẹ̀lú Kristi, bí àwa bá di ìpilẹ̀ṣẹ̀ ìgbẹ́kẹ̀lé wa mú ṣinṣin títí dé òpin.
15Nígbà tí a ń wí pé, “Lónìí bí ẹ̀yin bá gbọ́ ohùn rẹ̀, ẹ má sé ọkàn yin le, bí ìgbà ìṣọ̀tẹ̀.”
16Àwọn ta ni ó gbọ́ tí ó sì tún ṣọ̀tẹ̀? Kì í ha ṣe gbogbo àwọn tí o jáde kúrò ní Ejibiti ní abẹ́ àkóso Mose?
17Àwọn ta ni ó sì bínú sí fún ogójì ọdún? Kì í ha ṣe sí àwọn tí ó dẹ́ṣẹ̀, òkú àwọn tí ó sùn ní aginjù?
18Àwọn wo ni ó búra fún pé wọn kì yóò wọ inú ìsinmi òun, bí kò ṣe fún àwọn tí ó ṣe àìgbọ́ràn?
19Àwa sì rí i pé wọn kò lè wọ inú rẹ̀ nítorí àìgbàgbọ́.