Saamu 113:1-9
Biblica Open Yoruba Contemporary Bible (OYCB)
1Ẹ máa yin Olúwa. Yìn ín ẹ̀yin ìránṣẹ́ Olúwa, ẹ yin orúkọ Olúwa.
2Fi ìbùkún fún orúkọ Olúwa láti ìsinsin yìí lọ àti títí láéláé.
3Láti ìlà-oòrùn títí dé ìwọ̀ rẹ̀ orúkọ Olúwa ni kí a máa yìn.
4Olúwa ga lórí gbogbo orílẹ̀-èdè, àti ògo rẹ̀ lórí àwọn ọ̀run.
5Ta ló dàbí Olúwa Ọlọ́run wa, tí ó gbé ní ibi gíga.
6Tí ó rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ láti wò òun tí ó ń bẹ lọ́run, àti nínú ayé!
7Ó gbé òtòṣì dìde láti inú erùpẹ̀, àti pé ó gbé aláìní sókè láti inú ààtàn wá.
8Kí ó le mú un jókòó pẹ̀lú àwọn ọmọ-aládé àní pẹ̀lú àwọn ọmọ-aládé àwọn ènìyàn rẹ̀.
9Ó mú àgàn obìnrin gbé inú ilé, àti láti jẹ́ aláyọ̀ ìyá fún àwọn ọmọ rẹ̀. Ẹ yin Olúwa.