Saamu 116:1-19
Biblica Open Yoruba Contemporary Bible (OYCB)
1Èmi fẹ́ràn Olúwa, nítorí ó gbọ́ ohùn mi; ó gbọ́ ẹkún mi fún àánú.
2Nítorí ó yí etí rẹ̀ padà sí mi, èmi yóò máa pè é ni wọ́n ìgbà tí mo wà láààyè.
3Okùn ikú yí mi ká, ìrora isà òkú wá sórí mi; ìyọnu àti ìbànújẹ́ borí mi.
4Nígbà náà ni mo ké pe orúkọ Olúwa: “Olúwa, èmi bẹ̀ ọ́, gba ọkàn mi!”
5Olúwa ní oore-ọ̀fẹ́, ó sì ní òdodo; Ọlọ́run wa kún fún àánú.
6Olúwa pa àwọn ọlọ́kàn fífúyẹ́ mọ́ nígbà tí mo wà nínú àìní ńlá, ó gbà mí.
7Padà, ìwọ ọkàn mi, sí ibi ìsinmi rẹ, nítorí Olúwa ṣe dáradára sí ọ.
8Nítorí ìwọ, Olúwa, ti gba ọkàn mi kúrò lọ́wọ́ ikú, ojú mi kúrò lọ́wọ́ omijé, àti ẹsẹ̀ mi kúrò lọ́wọ́ ìṣubú,
9nítorí èmi yóò máa rìn níwájú Olúwa ní ilẹ̀ alààyè.
10Èmi gbàgbọ́; nítorí náà mo wí pé, “èmi rí ìpọ́njú púpọ̀”.
11Àti nínú ìdààmú mi mo wí pé, “Èké ni gbogbo ènìyàn”.
12Kí ni èmi yóò san fún Olúwa nítorí gbogbo rere rẹ̀ sí mi?
13Èmi yóò gbé ago ìgbàlà sókè èmi yóò sì máa ké pe orúkọ Olúwa.
14Èmi yóò mú ìlérí mi ṣẹ sí Olúwa ní ojú àwọn ènìyàn rẹ̀.
15Iyebíye ní ojú Olúwa àti ikú àwọn ẹni mímọ́ rẹ̀.
16Olúwa, nítòótọ́ ìránṣẹ́ rẹ ni mo jẹ́; èmi ni ìránṣẹ́ rẹ, ọmọ ìránṣẹ́bìnrin rẹ; ó ti tú mi sílẹ̀ nínú ìdè mi.
17Èmi yóò rú ẹbọ ọpẹ́ sí ọ èmi yóò sì ké pe orúkọ Olúwa.
18Èmi yóò mú ìlérí mi sẹ sí Olúwa ní ojú gbogbo àwọn ènìyàn rẹ̀,
19nínú àgbàlá ilé Olúwa ní àárín rẹ̀, ìwọ Jerusalẹmu. Ẹ yin Olúwa.