Saamu 120:1-7
Biblica Open Yoruba Contemporary Bible (OYCB)
1Èmi ké pe Olúwa nínú ìpọ́njú mi, ó sì dá mi lóhùn.
2Gbà mí, Olúwa, kúrò lọ́wọ́ ètè èké àti lọ́wọ́ ahọ́n ẹ̀tàn.
3Kí ni kí a fi fún ọ? Àti kí ni kí a túnṣe fún ọ, ìwọ ahọ́n ẹ̀tàn?
4Òun yóò bá ọ wí pẹ̀lú ọfà mímú ológun, pẹ̀lú ẹ̀yín iná igi ìgbálẹ̀.
5Ègbé ni fún mi tí èmi ṣe àtìpó ní Meṣeki, nítorí èmi gbé nínú àgọ́ ìlú Kedari!
6Ó ti pẹ́ tí èmi ti ń gbé láàrín àwọn tí ó kórìíra àlàáfíà.
7Ènìyàn àlàáfíà ni mí; ṣùgbọ́n nígbà tí mo bá sọ̀rọ̀, ogun ni dúró fun wọn.