Saamu 126:1-6
Biblica Open Yoruba Contemporary Bible (OYCB)
1Nígbà tí Olúwa mú ìkólọ Sioni padà, àwa dàbí ẹni tí ó ń lá àlá.
2Nígbà náà ni ẹnu wa kún fún ẹ̀rín, àti ahọ́n wa kọ orin; nígbà náà ni wọ́n wí nínú àwọn kèfèrí pé, Olúwa ṣe ohun ńlá fún wọn.
3Olúwa ṣe ohun ńlá fún wa; nítorí náà àwa ń yọ̀.
4Olúwa mú ìkólọ wa padà, bí ìṣàn omi ní gúúsù.
5Àwọn tí ń fi omijé fún irúgbìn yóò fi ayọ̀ ka.
6Ẹni tí ń fi ẹkún rìn lọ, tí ó sì gbé irúgbìn lọ́wọ́, lóòtítọ́, yóò fi ayọ̀ padà wá, yóò sì ru ìtí rẹ̀.