Saamu 150:1-6
Biblica Open Yoruba Contemporary Bible (OYCB)
1Ẹ fi ìyìn fún Olúwa. Ẹ fi ìyìn fún Ọlọ́run ní ibi mímọ́ rẹ̀, ẹ yìn ín nínú agbára ọ̀run rẹ̀.
2Ẹ yìn ín fún iṣẹ́ agbára rẹ̀. Ẹ yìn ín fún títóbi rẹ̀ tí ó tayọ̀.
3Ẹ fi ohùn ìpè yìn ín. Ẹ fi ohun èlò orin yìn ín.
4Ẹ fi ohun èlò orin àti ijó yìn ín fi ohun èlò orin olókùn àti ìpè yìn ín,
5Ẹ yìn ín pẹ̀lú aro olóhùn òkè, ẹ yìn ín lára aro olóhùn gooro.
6Jẹ́ kí gbogbo ohun tí ó ní ẹ̀mí yin Olúwa. Ẹ fi ìyìn fún Olúwa.