Saamu 29:1-11

Biblica Open Yoruba Contemporary Bible (OYCB)

1Ẹ fi fún Olúwa, ẹ̀yin ẹ̀dá ọ̀run, ẹ fi fún Olúwa, ògo àti alágbára.

2Fi fún Olúwa, àní ògo orúkọ rẹ̀; sin Olúwa nínú ẹwà ìwà mímọ́.

3Ohùn Olúwa n ré àwọn omi kọjá; Ọlọ́run ògo sán àrá, Olúwa san ara.

4Ohùn Olúwa ní agbára; ohùn Olúwa kún fún ọláńlá.

5Ohùn Olúwa fa igi kedari; Olúwa náà ló fọ́ igi kedari Lebanoni ya.

6Ó mú Lebanoni fo bí i ọmọ màlúù, àti Sirioni bí ọmọ àgbáǹréré.

7Ohùn Olúwa ń ya bí ọwọ́ iná mọ̀nà.

8Ohùn Olúwa ń mi aginjù. Olúwa mi aginjù Kadeṣi.

9Ohùn Olúwa ní ó lọ igi óákù, ó n mú abo àgbọ̀nrín bí, ó sì bọ́ igi igbó sí ìhòhò. Àti nínú tẹmpili rẹ̀ gbogbo ohùn wí pé, “Ògo!”

10Olúwa jókòó, Ó sì jẹ ọba lórí ìṣàn omi; Olúwa jókòó lórí ìtẹ́ gẹ́gẹ́ bí Ọba títí láéláé.

11Kí Olúwa fi agbára fún àwọn ènìyàn rẹ̀; bùkún àwọn ènìyàn rẹ̀ pẹ̀lú àlàáfíà.