Saamu 54:1-7
Biblica Open Yoruba Contemporary Bible (OYCB)
1Gbà mí, Ọlọ́run nípa orúkọ rẹ: dá mi láre nípa agbára rẹ.
2Gbọ́ àdúrà mi, Ọlọ́run; fi etí sí ọ̀rọ̀ ẹnu mi.
3Àwọn agbéraga àlejò dìde sí mí. Àwọn aninilára sì ń wá mi láti pa, àwọn ẹni tí kò ka Ọlọ́run sí ní ojú wọn.
4Kíyèsi i Ọlọ́run ni olùrànlọ́wọ́ mi; Olúwa ní ẹni tí ó mú mi dúró, pa wọ́n run nínú òtítọ́ rẹ.
5Jẹ́ kí ibi padà sẹ́yìn sí àwọn tí ń sọ̀rọ̀ ìbàjẹ́ sí mi; pa wọ́n run nínú òtítọ́ rẹ.
6Èmí yóò rú ẹbọ àtinúwá sí ọ, èmi yóò yin orúkọ rẹ, Olúwa, nítorí tí ó dára.
7Nítorí tí ó yọ mí kúrò nínú ibi gbogbo ojú mi ti wo ìṣẹ́gun lórí ọ̀tá mi.