Saamu 128:1-6
Biblica Open Yoruba Contemporary Bible (OYCB)
1Ìbùkún ni fún gbogbo ẹni tí ó bẹ̀rù Olúwa: tí ó sì ń rìn ní ọ̀nà rẹ̀.
2Nítorí tí ìwọ yóò jẹ iṣẹ́ ọwọ́ rẹ ìbùkún ni fún ọ; yóò sì dára fún ọ.
3Obìnrin rẹ yóò dàbí àjàrà rere eléso púpọ̀ ní àárín ilé rẹ; àwọn ọmọ rẹ yóò dàbí igi olifi tí ó yí tábìlì rẹ ká.
4Kíyèsi i pé, bẹ́ẹ̀ ni a ó bùsi i fún ọkùnrin náà, tí ó bẹ̀rù Olúwa.
5Kí Olúwa kí ó bùsi i fún ọ láti Sioni wá, kí ìwọ kí ó sì máa rí ìre Jerusalẹmu ní ọjọ́ ayé rẹ gbogbo.
6Bẹ́ẹ̀ ni kí ìwọ kí ó sì máa rí àti ọmọdọ́mọ rẹ. Láti àlàáfíà lára Israẹli.