Saamu 129:1-8
Biblica Open Yoruba Contemporary Bible (OYCB)
1“Ìgbà púpọ̀ ni wọ́n ti pọ́n mi lójú láti ìgbà èwe mi wá,” jẹ́ kí Israẹli kí ó wí nísinsin yìí;
2“Ìgbà púpọ̀ ni wọ́n ti pọ́n mi lójú láti ìgbà èwe mi wá; síbẹ̀ wọn kò tí ì borí mi.
3Àwọn awalẹ̀ walẹ̀ sí ẹ̀yìn mi: wọ́n sì la aporo wọn gígùn.
4Olódodo ni Olúwa: ó ti ké okùn àwọn ènìyàn búburú kúrò.”
5Kí gbogbo àwọn tí ó kórìíra Sioni kí ó dààmú, kí wọn kí ó sì yí ẹ̀yìn padà.
6Kí wọn kí ó dàbí koríko orí ilẹ̀ tí ó gbẹ dànù kí ó tó dàgbàsókè,
7èyí tí olóko pípa kó kún ọwọ́ rẹ̀: bẹ́ẹ̀ ni ẹni tí ń di ìtí, kó kún apá rẹ̀.
8Bẹ́ẹ̀ ni àwọn tí ń kọjá lọ kò wí pé, ìbùkún Olúwa kí ó pẹ̀lú yín: àwa ń súre fún yin ní orúkọ Olúwa.