Saamu 46:1-11

Biblica Open Yoruba Contemporary Bible (OYCB)

1Ọlọ́run ni ààbò àti agbára wa ó jẹ́ olùrànlọ́wọ́ ní ìgbà ìpọ́njú.

2Nítorí náà àwa kì yóò bẹ̀rù, bí a tilẹ̀ ṣí ayé ní ìdí, tí òkè sì ṣubú sínú Òkun.

3Tí omi rẹ̀ tilẹ̀ ń hó tí ó sì ń mì tí àwọn òkè ńlá tilẹ̀ ń mì pẹ̀lú ọwọ́ agbára rẹ̀. Sela.

4Odò ńlá kan wà tí ṣíṣàn rẹ̀ mú inú ìlú Ọlọ́run dùn, ibi mímọ́, níbi ti Ọ̀gá-ògo ń gbé.

5Ọlọ́run wà pẹ̀lú rẹ̀, kò ní yẹ̀: Ọlọ́run yóò ràn án lọ́wọ́ ní kùtùkùtù òwúrọ̀.

6Àwọn orílẹ̀-èdè ń bínú, àwọn ilẹ̀ ọba ṣubú, ó gbé ohun rẹ̀ sókè, ayé yọ̀.

7Olúwa àwọn ọmọ-ogun wà pẹ̀lú wa, Ọlọ́run Jakọbu ni ààbò wa.

8Ẹ wá wo iṣẹ́ Olúwa irú ahoro tí ó ṣe ní ayé.

9O mú ọ̀tẹ̀ tán de òpin ilẹ̀ ayé ó ṣẹ́ ọrun, ó sì gé ọ̀kọ̀ sí méjì ó fi kẹ̀kẹ́ ogun jóná.

10Ẹ dúró jẹ́ẹ́, kí ẹ sì mọ̀ pé èmi ní Ọlọ́run. A ó gbé mi ga nínú àwọn orílẹ̀-èdè, a ó gbé mi ga ní ayé.

11Olúwa àwọn ọmọ-ogun wà pẹ̀lú wa; Ọlọ́run Jakọbu sì ni ààbò wa.