Saamu 47:1-9

Biblica Open Yoruba Contemporary Bible (OYCB)

1Ẹ pàtẹ́wọ́, gbogbo ẹ̀yin ènìyàn ẹ hó sí Ọlọ́run pẹ̀lú orin ayọ̀ tó rinlẹ̀.

2Báwo ni Olúwa Ọ̀gá-ògo ti ní ẹ̀rù tó ọba ńlá lórí gbogbo ayé.

3Ṣe ìkápá àwọn orílẹ̀-èdè lábẹ́ wa àwọn ènìyàn lábẹ́ ẹsẹ̀ wa

4Ó mú ilẹ̀ ìní wa fún wa, ọlá Jakọbu, ẹni tí ó fẹ́ wa.

5Ọlọ́run tó gòkè lọ tí òun tayọ̀, Olúwa ti òun ti ariwo ìpè.

6Ẹ kọrin ìyìn sí Ọlọ́run, ẹ kọrin ìyìn. Ẹ kọrin ìyìn sí ọba wa, ẹ kọrin ìyìn!

7Nítorí Ọlọ́run ni ọba gbogbo ayé, ẹ kọrin ìyìn pẹ̀lú Saamu!

8Ọlọ́run jẹ ọba lórí gbogbo kèfèrí; Ọlọ́run jókòó lórí ìtẹ́ ìwà mímọ́ rẹ̀.

9Àwọn aládé ayé kó ara wọn jọ gẹ́gẹ́ bí ènìyàn Ọlọ́run Abrahamu nítorí asà ayé ti Ọlọ́run ni, òun ni ó ga jùlọ.