Saamu 95:1-11
Biblica Open Yoruba Contemporary Bible (OYCB)
1Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a kọ orin ayọ̀ sí Olúwa, ẹ jẹ́ kí a kígbe sókè sí àpáta ìgbàlà wa.
2Ẹ jẹ́ kí a wá sí iwájú rẹ̀ pẹ̀lú ọpẹ́ kí a sì pòkìkí rẹ̀ pẹ̀lú ohun èlò orin àti ìyìn.
3Nítorí Olúwa Ọlọ́run títóbi ni, ọba tí ó tóbi ju gbogbo òrìṣà lọ.
4Ní ọwọ́ rẹ̀ ni ọ̀gbun ilẹ̀ wà, ṣóńṣó orí òkè tirẹ̀ ní ṣe.
5Tirẹ̀ ni Òkun, nítorí òun ni ó dá a àti ọwọ́ rẹ̀ ni ó fi dá ìyàngbẹ ilẹ̀.
6Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a foríbalẹ̀ kí a sìn ín, ẹ jẹ́ kí a kúnlẹ̀ níwájú Olúwa ẹni tí ó dá wa,
7nítorí òun ni Ọlọ́run wa, àwa sì ni ènìyàn pápá rẹ̀, àti ọ̀wọ́ ẹran ni abẹ́ ìpamọ́ rẹ̀. Lónìí tí ìwọ bá gbọ́ ohùn rẹ̀,
8“Ẹ má ṣe sé ọkàn yín le gẹ́gẹ́ bí ẹ ti ṣe ní Meriba, àti bí ẹ ti ṣe ní ọjọ́ náà ní Massa ní aginjù,
9nígbà tí àwọn baba yín dán mi wò tí wọn wádìí mi, tí wọn sì rí iṣẹ́ mi.
10Fún ogójì ọdún ni èmi fi bínú sí ìran náà; mo wí pé, ‘Wọ́n jẹ́ ènìyàn tí ọkàn wọn ṣáko lọ wọn kò sì mọ ọ̀nà mi.’
11Nítorí náà ni mo kéde ìbúra nínú ìbínú mi, ‘Wọn kì yóò wọ ibi ìsinmi mi.’ ”