Saamu 96:1-13
Biblica Open Yoruba Contemporary Bible (OYCB)
1Ẹ kọrin tuntun sí Olúwa, ẹ kọrin sí Olúwa gbogbo ayé.
2Ẹ kọrin sí Olúwa, yin orúkọ rẹ̀ ẹ sọ ti ìgbàlà rẹ̀ ní ọjọ́ dé ọjọ́.
3Ẹ sọ ti ògo rẹ̀ láàrín àwọn orílẹ̀-èdè àti iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ láàrín gbogbo ènìyàn.
4Nítorí títóbi ní Olúwa ẹni tí ìyìn tọ́ sí; òun ní o yẹ kí a bẹ̀rù ju gbogbo òrìṣà lọ.
5Nítorí asán ni gbogbo àwọn òrìṣà orílẹ̀-èdè ṣùgbọ́n Olúwa dá àwọn ọ̀run.
6Ọlá àti ọláńlá wà ní iwájú rẹ̀ agbára àti ògo wà ní ibi mímọ́ rẹ̀.
7Ẹ fi fún Olúwa, ẹ̀yin ìbátan ènìyàn, ẹ fi agbára àti ògo fún Olúwa.
8Ẹ fi ògo tí ó tọ́ sí Olúwa fún un; ẹ mú ọrẹ wá, kí ẹ sì wá sí àgbàlá rẹ̀.
9Ẹ máa sin Olúwa nínú ẹwà ìwà mímọ́ rẹ̀; ẹ wárìrì níwájú rẹ̀ gbogbo ayé.
10Sọ láàrín àwọn orílẹ̀-èdè, “Olúwa jẹ ọba.” A fi ìdí ayé múlẹ̀, tí kò sì lè yí; ẹni tí yóò fi òtítọ́ ṣe ìdájọ́ ènìyàn.
11Jẹ́ kí àwọn ọ̀run kí ó yọ̀, kí ayé sì pariwo jẹ́ kí pápá òkun kí ó hó pẹ̀lú ohun gbogbo tí ń bẹ nínú rẹ̀.
12Jẹ́ kí oko kún fún ayọ̀, àti ohun gbogbo tí ń bẹ nínú rẹ̀; nígbà náà ni gbogbo igi igbó yóò máa yọ̀.
13Wọn yóò kọrin níwájú Olúwa, nítorí tí ó ń bọ̀ wá, ó ń bọ̀ wá ṣe ìdájọ́ ayé. Yóò fi òdodo ṣe ìdájọ́ ayé àti ti àwọn ènìyàn ni yóò fi òtítọ́ rẹ̀ ṣe.